1. ABRAHAMU si ṣí lati ibẹ̀ lọ si ilẹ ìha gusù, o si joko li agbedemeji Kadeṣi on Ṣuri; o si ṣe atipo ni Gerari.
2. Abrahamu si wi niti Sara aya rẹ̀ pe, Arabinrin mi ni: Abimeleki ọba Gerari si ranṣẹ, o si mu Sara.
3. Ṣugbọn Ọlọrun tọ̀ Abimeleki wá li ojuran li oru, o si wi fun u pe, kiyesi i, okú ni iwọ, nitori obinrin ti iwọ mu nì; nitori aya ọkunrin kan ni iṣe.