Gẹn 18:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OLUWA si farahàn a ni igbo Mamre: on si joko li ẹnu-ọ̀na agọ́ ni imõru ọjọ́:

2. O si gbé oju rẹ̀ soke, o wò, si kiyesi i, ọkunrin mẹta duro li ẹba ọdọ rẹ̀: nigbati o si ri wọn, o sure lati ẹnu-ọ̀na agọ́ lọ ipade wọn, o si tẹriba silẹ.

3. O si wipe, OLUWA mi, njẹ bi mo ba ri ore-ọfẹ li oju rẹ, emi bẹ̀ ọ, máṣe kọja lọ kuro lọdọ ọmọ-ọdọ rẹ:

4. Jẹ ki a mu omi diẹ wá nisisiyi, ki ẹnyin ki o si wẹ̀ ẹsẹ̀ nyin, ki ẹnyin ki o si simi labẹ igi:

5. Emi o si mu onjẹ diẹ wá, ki ẹnyin si fi ọkàn nyin balẹ; lẹhin eyini ki ẹnyin ma kọja lọ: njẹ nitorina li ẹnyin ṣe tọ̀ ọmọ-ọdọ nyin wá. Nwọn si wipe, Ṣe bẹ̃ bi iwọ ti wi.

6. Abrahamu si yara tọ̀ Sara lọ ninu agọ́, o wipe, Yara mu òṣuwọn iyẹfun daradara mẹta, ki o pò o, ki o si dín akara.

7. Abrahamu si sure lọ sinu agbo, o si mu ẹgbọrọ-malu kan ti o rọ̀ ti o dara, o fi fun ọmọkunrin kan; on si yara lati sè e.

8. O si mu orí-amọ́, ati wàra, ati ẹgbọrọ malu ti o sè, o si gbé e kalẹ niwaju wọn: on si duro tì wọn li abẹ igi na, nwọn si jẹ ẹ.

Gẹn 18