13. Ẹniti a bí ni ile rẹ, ati ẹniti a fi owo rẹ rà, a kò le ṣe alaikọ ọ ni ilà: bẹ̃ni majẹmu mi yio si wà li ara nyin ni majẹmu aiyeraiye.
14. Ati ọmọkunrin alaikọlà ti a kò kọ ni ilà ara rẹ̀, ọkàn na li a o si ké kuro ninu awọn enia rẹ̀, o dà majẹmu mi.
15. Ọlọrun si wi fun Abrahamu pe, Bi o ṣe ti Sarai, aya rẹ nì, iwọ ki yio pè orukọ rẹ̀ ni Sarai mọ́, bikoṣe Sara li orukọ rẹ̀ yio ma jẹ.
16. Emi o si busi i fun u, emi o si bùn ọ li ọmọkunrin kan pẹlu lati ọdọ rẹ̀ wá, bẹ̃li emi o si busi i fun u, on o si ṣe iya ọ̀pọ orilẹ-ède; awọn ọba enia ni yio ti ọdọ rẹ̀ wá.
17. Nigbana li Abrahamu dojubolẹ, o si rẹrin, o si wi li ọkàn rẹ̀ pe, A o ha bímọ fun ẹni ọgọrun ọdún? Sara ti iṣe ẹni ãdọrun ọdún yio ha bímọ bi?
18. Abrahamu si wi fun Ọlọrun pe, Ki Iṣmaeli ki o wà lãye niwaju rẹ!
19. Ọlọrun si wipe, Sara, aya rẹ, yio bí ọmọkunrin kan fun ọ nitõtọ; iwọ o si sọ orukọ rẹ̀ ni Isaaki: emi o fi idi majẹmu mi mulẹ pẹlu rẹ̀, ni majẹmu aiyeraiye, ati pẹlu irú-ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀.
20. Emi si ti gbọ́ adura rẹ fun Iṣmaeli: kiyesi i, emi o si busi i fun u, emi o si mu u bisi i, emi o si sọ ọ di pupọ̀ gidigidi; ijoye mejila ni on o bí, emi o si sọ ọ di orilẹ-ède nla:
21. Ṣugbọn majẹmu mi li emi o ba Isaaki dá, ẹniti Sara yio bí fun ọ li akoko iwoyi amọ́dun.
22. O si fi i silẹ li ọ̀rọ iba a sọ, Ọlọrun si lọ soke kuro lọdọ Abrahamu.
23. Abrahamu si mu Iṣmaeli, ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati gbogbo awọn ọmọ-ọdọ ọkunrin ti a bí ni ile rẹ̀, ati gbogbo awọn ti a fi owo rẹ̀ rà, gbogbo ẹniti iṣe ọkunrin ninu awọn enia ile Abrahamu; o si kọ wọn ni ilà ara li ọjọ́ na gan, bi Ọlọrun ti sọ fun u.
24. Abrahamu si jẹ ẹni ọkandilọgọrun ọdún, nigbati a kọ ọ ni ilà ara rẹ̀.