Gẹn 16:13-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. O si pè orukọ OLUWA ti o ba a sọ̀rọ ni, Iwọ Ọlọrun ti o ri mi: nitori ti o wipe, Emi ha wá ẹniti o ri mi kiri nihin?

14. Nitori na li a ṣe npè kanga na ni Beer-lahai-roi: kiyesi i, o wà li agbedemeji Kadeṣi on Beredi.

15. Hagari si bí ọmọkunrin kan fun Abramu: Abramu si pè orukọ ọmọ ti Hagari bí ni Iṣmaeli.

16. Abramu si jẹ ẹni ẹrindilãdọrun ọdún, nigbati Hagari bí Iṣmaeli fun Abramu.

Gẹn 16