1. LẸHIN nkan wọnyi ọ̀rọ OLUWA tọ̀ Abramu wá li ojuran, wipe, Má bẹ̀ru, Abramu; Emi li asà rẹ, ère nla rẹ gidigidi.
2. Abramu si wipe, OLUWA Ọlọrun, kini iwọ o fi fun mi, emi sa nlọ li ailọmọ, Elieseri ti Damasku yi si ni ẹniti o ni ile mi?
3. Abramu si wipe, Wo o emi ni iwọ kò fi irú-ọmọ fun: si wo o, ẹrú ti a bi ni ile mi ni yio jẹ arolé.
4. Si wo o, ọ̀rọ OLUWA tọ̀ ọ wá, wipe, Eleyi ki yio ṣe arole rẹ; bikoṣe ẹniti yio ti inu ara rẹ jade, on ni yio ṣe arole rẹ.
5. O si mu u jade wá si gbangba, o si wi pe, Gboju wò oke ọrun nisisiyi, ki o si kà irawọ bi iwọ ba le kà wọn: o si wi fun u pe, Bẹ̃ni irú-ọmọ rẹ yio ri.
6. O si gba OLUWA gbọ́; on si kà a si fun u li ododo.
7. O si wi fun u pe, Emi li OLUWA ti o mu ọ jade lati Uri ti Kaldea wá, lati fi ilẹ yi fun ọ lati jogun rẹ̀.
8. O si wipe, OLUWA Ọlọrun, nipa bawo li emi o fi mọ̀ pe emi o jogun rẹ̀?
9. O si wi fun u pe, Mu ẹgbọrọ malu ọlọdun mẹta fun mi wá, ati ewurẹ ọlọdun mẹta, ati àgbo ọlọdun mẹta, ati oriri kan, ati ọmọ ẹiyẹle kan.
10. O si mu gbogbo nkan wọnyi wá sọdọ rẹ̀, o si là wọn li agbedemeji, o si fi ẹ̀la ekini kọju si ekeji: bikoṣe awọn ẹiyẹ ni kò là.
11. Nigbati awọn ẹiyẹ si sọkalẹ wá si ori okú wọnyi, Abramu lé wọn kuro.
12. O si ṣe nigbati õrùn nwọ̀ lọ, orun ìjika kùn Abramu; si kiyesi i, ẹ̀ru bà a, òkunkun biribiri si bò o.
13. On si wi fun Abramu pe, Mọ̀ nitõtọ pe irú-ọmọ rẹ yio ṣe alejo ni ilẹ ti ki iṣe ti wọn, nwọn o si sìn wọn, nwọn o si jẹ wọn ni íya ni irinwo ọdún;