Gẹn 14:13-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Ẹnikan ti o sá asalà de, o si rò fun Abramu Heberu nì; on sa tẹdo ni igbo Mamre ara Amori, arakunrin Eṣkoli ati arakunrin Aneri: awọn wọnyi li o mba Abramu ṣe pọ̀.

14. Nigbati Abramu gbọ́ pe a dì arakunrin on ni igbekun, o kó awọn ọmọ ọdọ rẹ̀ ti a ti kọ́, ti a bí ni ile rẹ̀ jade, ọrindinirinwo enia o din meji, o si lepa wọn de Dani.

15. O si pín ara rẹ̀, on, pẹlu awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, si wọn li oru, o si kọlù wọn, o si lépa wọn de Hoba, ti o wà li apa òsi Damasku:

16. O si gbà gbogbo ẹrù na pada, o si gbà Loti arakunrin rẹ̀ pada pẹlu, ati ẹrù rẹ̀, ati awọn obinrin pẹlu, ati awọn enia.

17. Ọba Sodomu si jade lọ ipade rẹ̀ li àbọ iṣẹgun Kedorlaomeri ati awọn ọba ti o pẹlu rẹ̀, li afonifoji Ṣafe, ti iṣe Afonifoji Ọba.

18. Melkisedeki ọba Salemu si mu onjẹ ati ọti waini jade wá: on a si ma ṣe alufa Ọlọrun Ọga-ogo.

19. O si súre fun u, o si wipe, Ibukun ni fun Abramu, ti Ọlọrun ọga-ogo, ẹniti o ni ọrun on aiye.

20. Olubukun si li Ọlọrun ọga-ogo ti o fi awọn ọta rẹ le ọ lọwọ. On si dá idamẹwa ohun gbogbo fun u.

21. Ọba Sodomu si wi fun Abramu pe, Dá awọn enia fun mi, ki o si mu ẹrù fun ara rẹ.

22. Abramu si wi fun ọba Sodomu pe, Mo ti gbé ọwọ́ mi soke si OLUWA, Ọlọrun ọga-ogo, ti o ni ọrun on aiye,

23. Pe, emi ki yio mu lati fọnran owu titi dé okùn bàta, ati pe, emi kì yio mu ohun kan ti iṣe tirẹ, ki iwọ ki o má ba wipe, Mo sọ Abramu di ọlọrọ̀:

24. Bikoṣe kìki eyiti awọn ọdọmọkunrin ti jẹ, ati ipín ti awọn ọkunrin ti o ba mi lọ; Aneri, Eṣkoli, ati Mamre; jẹ ki nwọn ki o mu ipín ti wọn.

Gẹn 14