1. ABRAMU si goke lati Egipti wá, on, ati aya rẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ni, ati Loti pẹlu rẹ̀, si ìha gusu.
2. Abramu si là gidigidi, li ẹran-ọ̀sin, ni fadaka, ati ni wurà.
3. O si nrìn ìrin rẹ̀ lati ìha gusu lọ titi o si fi de Beteli, de ibi ti agọ́ rẹ̀ ti wà ni iṣaju, lagbedemeji Beteli on Hai.
4. Si ibi pẹpẹ ti o ti tẹ́ nibẹ̀ ni iṣaju: nibẹ̀ li Abramu si nkepè orukọ OLUWA.
5. Ati Loti pẹlu, ti o ba Abramu lọ, ni agbo-ẹran, ati ọwọ́-ẹran, ati agọ́.
6. Ilẹ na kò si le igbà wọn, ki nwọn ki o le igbé pọ̀: nitori ini wọn pọ̀, bẹ̃nì nwọn kò si le gbé pọ̀.
7. Bẹ̃ni gbolohùn asọ̀ si wà lãrin awọn darandaran Abramu, ati awọn darandaran Loti: ati awọn ara Kenaani ati awọn enia Perissi ngbé ilẹ na ni ìgba na.
8. Abramu si wi fun Loti pe, Emi bẹ̀ ọ, máṣe jẹ ki gbolohùn asọ̀ ki o wà lãrin temi tirẹ, ati lãrin awọn darandaran mi, ati awọn darandaran rẹ; nitori pe ará li awa iṣe.