Gẹn 11:8-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Bẹ̃li OLUWA tú wọn ká lati ibẹ̀ lọ si ori ilẹ gbogbo: nwọn si ṣíwọ ilu ti nwọn ntẹdó.

9. Nitorina li a ṣe npè orukọ ilu na ni Babeli; nitori ibẹ̀ li OLUWA gbe dà ède araiye rú, lati ibẹ̀ lọ OLUWA si tú wọn ká kiri si ori ilẹ gbogbo.

10. Wọnyi ni iran Ṣemu: Ṣemu jẹ ẹni ọgọrun ọdún, o si bí Arfaksadi li ọdún keji lẹhin kíkun-omi.

11. Ṣemu si wà li ẹ̃dẹgbẹta ọdún, lẹhin igbati o bí Arfaksadi tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin.

12. Arfaksadi si wà li arundilogoji ọdún, o si bí Ṣela:

13. Arfaksadi si wà ni irinwo ọdún o le mẹta, lẹhin igbati o bí Ṣela tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin.

14. Ṣela si wà ni ọgbọ̀n ọdún, o si bí Eberi:

15. Ṣela si wà ni irinwo ọdún o le mẹta lẹhin ti o bí Eberi tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin.

16. Eberi si wà li ọgbọ̀n ọdún o le mẹrin, o si bí Pelegi:

17. Eberi si wà ni irinwo ọdún o le ọgbọ̀n lẹhin igbati o bí Pelegi tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin.

18. Pelegi si wà li ọgbọ̀n ọdún, o si bì Reu:

19. Pelegi si wà ni igba ọdún o le mẹsan lẹhin igbati o bí Reu tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin.

20. Reu si wà li ọgbọ̀n ọdún o le meji, o si bí Serugu:

21. Reu si wà ni igba ọdún o le meje, lẹhin igbati o bí Serugu tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin.

22. Serugu si wà li ọgbọ̀n ọdún, o si bí Nahori:

23. Serugu si wà ni igba ọdún, lẹhin igba ti o bí Nahori tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin.

24. Nahori si jẹ ẹni ọdún mọkanlelọgbọ̀n o si bí Tera:

25. Nahori si wà li ọgọfa ọdún o dí ọkan, lẹhin igbati o bí Tera tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin.

26. Tera si wà li ãdọrin ọdún, o si bí Abramu, Nahori, ati Harani.

27. Iran Tera si li eyi: Tera bi Abramu, Nahori, ati Harani; Harani si bí Loti.

Gẹn 11