Gẹn 11:8-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Bẹ̃li OLUWA tú wọn ká lati ibẹ̀ lọ si ori ilẹ gbogbo: nwọn si ṣíwọ ilu ti nwọn ntẹdó.

9. Nitorina li a ṣe npè orukọ ilu na ni Babeli; nitori ibẹ̀ li OLUWA gbe dà ède araiye rú, lati ibẹ̀ lọ OLUWA si tú wọn ká kiri si ori ilẹ gbogbo.

10. Wọnyi ni iran Ṣemu: Ṣemu jẹ ẹni ọgọrun ọdún, o si bí Arfaksadi li ọdún keji lẹhin kíkun-omi.

11. Ṣemu si wà li ẹ̃dẹgbẹta ọdún, lẹhin igbati o bí Arfaksadi tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin.

12. Arfaksadi si wà li arundilogoji ọdún, o si bí Ṣela:

13. Arfaksadi si wà ni irinwo ọdún o le mẹta, lẹhin igbati o bí Ṣela tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin.

14. Ṣela si wà ni ọgbọ̀n ọdún, o si bí Eberi:

15. Ṣela si wà ni irinwo ọdún o le mẹta lẹhin ti o bí Eberi tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin.

16. Eberi si wà li ọgbọ̀n ọdún o le mẹrin, o si bí Pelegi:

Gẹn 11