19. Pelegi si wà ni igba ọdún o le mẹsan lẹhin igbati o bí Reu tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin.
20. Reu si wà li ọgbọ̀n ọdún o le meji, o si bí Serugu:
21. Reu si wà ni igba ọdún o le meje, lẹhin igbati o bí Serugu tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin.
22. Serugu si wà li ọgbọ̀n ọdún, o si bí Nahori:
23. Serugu si wà ni igba ọdún, lẹhin igba ti o bí Nahori tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin.
24. Nahori si jẹ ẹni ọdún mọkanlelọgbọ̀n o si bí Tera:
25. Nahori si wà li ọgọfa ọdún o dí ọkan, lẹhin igbati o bí Tera tan, o si bí ọmọkunrin ati ọmọbinrin.
26. Tera si wà li ãdọrin ọdún, o si bí Abramu, Nahori, ati Harani.
27. Iran Tera si li eyi: Tera bi Abramu, Nahori, ati Harani; Harani si bí Loti.
28. Harani si kú ṣaju Tera baba rẹ̀, ni ilẹ ibi rẹ̀, ni Uri ti Kaldea.
29. Ati Abramu ati Nahor si fẹ aya fun ara wọn: orukọ aya Abramu ni Sarai; ati orukọ aya Nahori ni Milka, ọmọbinrin Harani, baba Milka, ati baba Iska.
30. Ṣugbọn Sarai yàgan; kò li ọmọ.