Gẹn 10:22-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

22. Awọn ọmọ Ṣemu: Elamu, ati Aṣṣuri, ati Arfaksadi, ati Ludi, ati Aramu.

23. Ati awọn ọmọ Aramu; Usi, ati Huli, ati Geteri, ati Maṣi.

24. Arfaksadi si bí Ṣela; Ṣela si bí Eberi.

25. Ati fun Eberi li a bí ọmọkunrin meji; orukọ ekini ni Pelegi; nitori nigba ọjọ́ rẹ̀ ni ilẹ yà; orukọ arakunrin rẹ̀ ni Joktani.

26. Joktani si bí Almodadi, ati Ṣelefi, ati Hasarmafeti, ati Jera,

27. Ati Hadoramu, ati Usali, ati Dikla,

28. Ati Obali, ati Abimaeli, ati Ṣeba,

29. Ati Ofiri, ati Hafila, ati Jobabu: gbogbo awọn wọnyi li ọmọ Joktani.

30. Ibugbe wọn si ti Meṣa lọ, bi iwọ ti nlọ si Sefari, oke kan ni ìla-õrùn.

31. Awọn wọnyi li ọmọ Ṣemu, gẹgẹ bi idile wọn, gẹgẹ bi ohùn wọn, ni ilẹ wọn, li orilẹ-ède wọn.

Gẹn 10