Gẹn 10:20-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. Awọn wọnyi li ọmọ Hamu, gẹgẹ bi idile wọn, gẹgẹ bi ohùn wọn, ni ilẹ wọn, ati li orilẹ-ède wọn.

21. Fun Ṣemu pẹlu, baba gbogbo awọn ọmọ Eberi, ẹgbọn Jafeti ati fun on li a bimọ.

22. Awọn ọmọ Ṣemu: Elamu, ati Aṣṣuri, ati Arfaksadi, ati Ludi, ati Aramu.

23. Ati awọn ọmọ Aramu; Usi, ati Huli, ati Geteri, ati Maṣi.

24. Arfaksadi si bí Ṣela; Ṣela si bí Eberi.

25. Ati fun Eberi li a bí ọmọkunrin meji; orukọ ekini ni Pelegi; nitori nigba ọjọ́ rẹ̀ ni ilẹ yà; orukọ arakunrin rẹ̀ ni Joktani.

26. Joktani si bí Almodadi, ati Ṣelefi, ati Hasarmafeti, ati Jera,

27. Ati Hadoramu, ati Usali, ati Dikla,

28. Ati Obali, ati Abimaeli, ati Ṣeba,

Gẹn 10