Gẹn 10:11-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Lati ilẹ na ni Aṣṣuri ti jade lọ, o si tẹ̀ Ninefe, ati ilu Rehoboti, ati Kala dó.

12. Ati Reseni lagbedemeji Ninefe on Kala: eyi na ni ilu nla.

13. Misraimu si bí Ludimu, ati Anamimu, ati Lehabimu, ati Naftuhimu,

14. Ati Patrusimu, ati Kasluhimu (lati ọdọ ẹniti Filistimu ti wá), ati Kaftorimu.

15. Kenaani si bí Sidoni akọbi rẹ̀, ati Heti,

16. Ati awọn ara Jebusi, ati awọn ara Amori, ati awọn ara Girgaṣi,

17. Ati awọn ara Hiffi, ati awọn ara Arki, ati awọn ara Sini,

18. Ati awọn ara Arfadi, ati awọn ara Semari, ati awọn ara Hamati; lẹhin eyini ni idile awọn ara Kenaani tàn kalẹ.

19. Ati àgbegbe awọn ara Kenaani ni Sidoni, bi o ti mbọ̀wa Gerari, titi de Gasa; bi o ti nlọ si Sodomu, ati Gomorra, ati Adma, ati Seboimu, titi dé Laṣa.

Gẹn 10