Gẹn 1:8-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Ọlọrun si pè ofurufu ni Ọrun. Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ keji.

9. Ọlọrun si wipe, Ki omi abẹ ọrun ki o wọjọ pọ̀ si ibi kan, ki iyangbẹ ilẹ ki o si hàn: o si ri bẹ̃.

10. Ọlọrun si pè iyangbẹ ilẹ ni Ilẹ; o si pè iwọjọpọ̀ omi ni Okun: Ọlọrun si ri pe o dara.

11. Ọlọrun si wipe, Ki ilẹ ki o hù oko, eweko ti yio ma so eso, ati igi eleso ti yio ma so eso ni irú tirẹ̀, ti o ni irugbin ninu lori ilẹ: o si ri bẹ̃.

12. Ilẹ si sú koriko jade, eweko ti nso eso ni irú tirẹ̀, ati igi ti nso eso, ti o ni irugbin ninu ni irú tirẹ̀: Ọlọrun si ri pe o dara.

13. Ati aṣalẹ ati owurọ̀ o di ọjọ́ kẹta.

14. Ọlọrun si wipe, Ki awọn imọlẹ ki o wà li ofurufu ọrun, lati pàla ọsán on oru; ki nwọn ki o si ma wà fun àmi, ati fun akoko, ati fun ọjọ́, ati fun ọdún:

15. Ki nwọn ki o si jẹ́ imọlẹ li ofurufu ọrun, lati mọlẹ sori ilẹ: o si ri bẹ̃.

16. Ọlọrun si dá imọlẹ nla meji; imọlẹ ti o tobi lati ṣe akoso ọsán, ati imọlẹ ti o kere lati ṣe akoso oru: o si dá awọn irawọ pẹlu.

Gẹn 1