Gal 5:13-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Nitori a ti pè nyin si omnira, ará; kiki pe ki ẹ máṣe lò omnira nyin fun àye sipa ti ara, ṣugbọn ẹ mã fi ifẹ sìn ọmọnikeji nyin.

14. Nitoripe a kó gbogbo ofin já ninu ọ̀rọ kan, ani ninu eyi pe; Iwọ fẹ ọmọnikeji rẹ bi ara rẹ.

15. Ṣugbọn bi ẹnyin ba mbù ara nyin ṣán, ti ẹ si njẹ ara nyin run, ẹ kiyesara ki ẹ máṣe pa ara nyin run.

16. Njẹ mo ni, Ẹ ma rìn nipa ti Ẹmí, ẹnyin kì yio si mu ifẹkufẹ ti ara ṣẹ.

17. Nitoriti ara nṣe ifẹkufẹ lodi si Ẹmí, ati Ẹmí lodi si ara: awọn wọnyi si lodi si ara wọn; ki ẹ má ba le ṣe ohun ti ẹnyin nfẹ.

18. Ṣugbọn bi a ba nti ọwọ Ẹmí ṣamọna nyin, ẹnyin kò si labẹ ofin.

Gal 5