Filp 3:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. LI akotan, ará, ẹ mã yọ̀ ninu Oluwa. Kì iṣe inira fun mi lati kọwe ohun kanna si nyin, ṣugbọn fun nyin o jẹ ailewu.

2. Ẹ kiyesara lọdọ awọn ajá, ẹ kiyesara lọdọ awọn oniṣẹ-buburu, ẹ kiyesara lọdọ awọn onilà.

3. Nitori awa ni onilà, ti nsìn Ọlọrun nipa ti Ẹmí, awa si nṣogo ninu Kristi Jesu, awa kò si ni igbẹkẹle ninu ẹran-ara;

4. Bi emi tikarami tilẹ ni igbẹkẹle ninu ara. Bi ẹnikẹni ba rò pe on ni igbẹkẹle ninu ara, temi tilẹ ju:

5. Ẹniti a kọ nilà ni ijọ kẹjọ, lati inu kukuté Israeli wá, lati inu ẹ̀ya Benjamini, Heberu lati inu Heberu wá; niti ofin, Farisi li emi;

6. Niti itara, emi nṣe inunibini si ijọ; niti ododo ti o wà ninu ofin, mo jẹ alailẹgan.

7. Ṣugbọn ohunkohun ti o ti jasi ère fun mi, awọn ni mo ti kà si òfo nitori Kristi.

8. Nitõtọ laiṣe ani-ani mo si kà ohun gbogbo si òfo nitori itayọ ìmọ Kristi Jesu Oluwa mi: nitori ẹniti mo ti ṣòfo ohun gbogbo, mo si kà wọn si igbẹ́, ki emi ki o le jère Kristi,

9. Ki a si le bá mi ninu rẹ̀, li aini ododo ti emi tikarami, ti o ti inu ofin wá, ṣugbọn eyi ti o ti inu igbagbọ wá ninu Kristi, ododo ti Ọlọrun nipasẹ igbagbọ́:

10. Ki emi ki o le mọ̀ ọ, ati agbara ajinde rẹ̀, ati alabapin ninu ìya rẹ̀, nigbati mo ba faramọ ikú rẹ̀;

11. Bi o le ṣe ki emi ki o le de ibi ajinde awọn okú.

Filp 3