Est 6:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Li oru na ọba kò le sùn, o si paṣẹ pe, ki a mu iwe iranti, ani irohin awọn ọjọ wá, a si kà wọn niwaju ọba.

2. A si ri pe, ati kọ ọ pe, Mordekai ti sọ ti Bigtani, ati Tereṣi, awọn ìwẹfa ọba meji, oluṣọ iloro, awọn ẹniti nwá ọ̀na lati gbe ọwọ le Ahaswerusi ọba.

3. Ọba si wi pe, Iyìn ati ọlá wo li a fi fun Mordekai nitori eyi? Nigbana ni awọn ọmọ-ọdọ ọba ti nṣe iranṣẹ fun u wi pe, a kò ṣe nkankan fun u.

4. Ọba si wi pe, Tani mbẹ ni àgbala? Hamani si ti de àgbala akọkàn ile ọba, lati ba ọba sọ ọ lati so Mordekai rọ̀ sori igi giga ti o ti rì fun u.

5. Awọn ọmọ-ọdọ ọba si wi fun u pe, Sa wò o, Hamani duro ni agbala, Ọba si wi pe, jẹ ki o wọle.

Est 6