Est 5:10-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Ṣugbọn Hamani kó ara rẹ̀ ni ijanu: nigbati o si de ile, o ranṣẹ lọ ipè awọn ọrẹ rẹ̀, ati Sereṣi aya rẹ̀.

11. Hamani si ròhin ogo ọrọ̀ rẹ̀, ati ọ̀pọlọpọ awọn ọmọ rẹ̀, ati ninu ohun gbogbo ti ọba fi gbe e ga, ati bi o ti gbe on ga jù awọn ijoye, ati awọn ọmọ-ọdọ ọba lọ.

12. Hamani si wi pẹlu pe, ani Esteri ayaba kò mu ki ẹnikẹni ki o ba ọba wá si ibi àse ti o ti sè bikoṣe emi nikan; li ọla ẹ̀wẹ li a si tun pè mi pẹlu ọba lati wá si ọdọ rẹ̀,

13. Ṣugbọn gbogbo wọnyi kò di nkankan fun mi, niwọ̀n igbati mo ba ri Mordekai, ara Juda nì, ti o joko li ẹnu ọ̀na ile ọba.

14. Nigbana ni Sereṣi aya rẹ̀, ati gbogbo awọn ọrẹ rẹ̀ wi fun u pe, Jẹ ki a rì igi kan, ki o ga ni ãdọta igbọnwọ, ati li ọla ni ki o ba ọba sọ ọ ki a so Mordekai rọ̀ nibẹ: iwọ̀ o si fi ayọ̀ ba ọba lọ si ibi àse. Nkan yi dùn mọ Hamani, o si rì igi na.

Est 5