Est 1:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si ṣe li ọjọ Ahaswerusi, (eyi ni Ahaswerusi ti o jọba lati India, ani titi o fi de Etiopia, lori ẹtadiladoje ìgberiko:)

2. Li ọjọ wọnni, nigbati Ahaswerusi, ọba, joko lori itẹ ijọba rẹ̀, ti o wà ni Ṣuṣani, ãfin.

3. Li ọdun kẹta ijọba rẹ̀, o sè àse kan fun gbogbo awọn ijoye ati awọn iranṣẹ rẹ̀; awọn balogun Persia ati Media, awọn ọlọla, ati awọn olori ìgberiko wọnni wà niwaju rẹ̀:

4. Nigbati o fi ọrọ̀ ijọba rẹ̀ ti o logo, ati ọṣọ iyebiye ọlanla rẹ̀ han lọjọ pipọ̀, ani li ọgọsan ọjọ.

5. Nigbati ọjọ wọnyi si pari, ọba sè àse kan li ọjọ meje fun gbogbo awọn enia ti a ri ni Ṣuṣani ãfin, ati àgba ati ewe ni agbala ọgba ãfin ọba.

6. Nibiti a gbe ta aṣọ àla daradara, aṣọ alaro, ati òféfe, ti a fi okùn ọ̀gbọ daradara, ati elesè aluko dimu mọ oruka fadaka, ati ọwọ̀n okuta marbili: wura ati fadaka ni irọgbọku, ti o wà lori ilẹ ti a fi okuta alabastari, marbili, ilẹkẹ daradara, ati okuta dudu tẹ́.

7. Ninu ago wura li a si nfun wọn mu, (awọn ohun elo na si yatọ si ara wọn) ati ọti-waini ọba li ọ̀pọlọpọ gẹgẹ bi ọwọ ọba ti to.

8. Gẹgẹ bi aṣẹ si ni mimu na; ẹnikẹni kò fi ipa rọ̀ ni: nitori bẹ̃ni ọba ti fi aṣẹ fun gbogbo awọn olori ile rẹ̀, ki nwọn ki o le ṣe gẹgẹ bi ifẹ olukuluku.

Est 1