Esr 3:6-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Lati ọjọ ikini oṣu keje ni nwọn bẹ̀rẹ lati ma rú ẹbọ sisun si Oluwa. Ṣugbọn a kò ti ifi ipilẹ tempili Oluwa lelẹ.

7. Nwọn si fi owo fun awọn ọmọle pẹlu, ati fun awọn gbẹna-gbẹna, pẹlu onjẹ, ati ohun mimu, ati ororo, fun awọn ara Sidoni, ati fun awọn ara Tire, lati mu igi kedari ti Lebanoni wá si okun Joppa, gẹgẹ bi aṣẹ ti nwọn gbà lati ọwọ Kirusi ọba Persia.

8. Li ọdun keji ti nwọn wá si ile Ọlọrun ni Jerusalemu, li oṣu keji, ni Serubbabeli, ọmọ Ṣealtieli bẹ̀rẹ, ati Jeṣua ọmọ Josadaki, ati iyokù awọn arakunrin wọn, awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi, ati gbogbo awọn ti o ti ìgbekun jade wá si Jerusalemu, nwọn si yan awọn ọmọ Lefi lati ẹni ogun ọdun ati jù bẹ̃ lọ lati ma tọju iṣẹ ile Oluwa.

9. Nigbana ni Jeṣua pẹlu awọn ọmọkunrin rẹ̀ ati awọn arakunrin rẹ̀, Kadmieli ati awọn ọmọ rẹ̀, awọn ọmọ Juda, jumọ dide bi ẹnikanṣoṣo lati ma tọju awọn oniṣẹ ninu ile Ọlọrun; awọn ọmọ Henadadi, pẹlu awọn ọmọ wọn, ati arakunrin wọn, awọn ọmọ Lefi.

Esr 3