Esek 5:5-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Eyi ni Jerusalemu: Emi ti gbe e kalẹ li ãrin awọn orilẹ-ède, ati awọn ilẹ ti o wà yi i ka kiri.

6. O si ti pa idajọ mi dà si buburu ju awọn orilẹ-ède lọ, ati ilana mi ju ilẹ ti o yi i kakiri: nitori nwọn ti kọ̀ idajọ ati ilana mi, nwọn kò rìn ninu wọn.

7. Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi: Nitori ti ẹnyin ṣe ju awọn orilẹ-ède ti o yi nyin ka kiri lọ, ti ẹnyin kò rìn ninu ilana mi, ti ẹ kò pa idajọ mi mọ, ti ẹ kò si ṣe gẹgẹ bi idajọ awọn orilẹ-ède ti o yi nyin ka kiri.

8. Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi: kiye si i, Emi, ani Emi, doju kọ ọ, emi o si ṣe idajọ li ãrin rẹ li oju awọn orilẹ-ède.

9. Emi o si ṣe ninu rẹ ohun ti emi kò ṣe ri, iru eyi ti emi kì yio si ṣe mọ, nitori gbogbo ohun irira rẹ.

10. Nitorina awọn baba yio jẹ awọn ọmọ li ãrin rẹ, ati awọn ọmọ yio si jẹ awọn baba wọn; emi o si ṣe idajọ ninu rẹ, ati gbogbo iyokù rẹ li emi o tuka si gbogbo ẹfũfù.

11. Nitorina Oluwa Ọlọrun wipe, Bi mo ti wà; Nitõtọ, nitori ti iwọ ti sọ ibi mimọ́ mi di aimọ́ nipa ohun ẹgbin rẹ, ati pẹlu gbogbo ohun irira rẹ, nitori na li emi o ṣe dín ọ kù, oju mi kì yio dasi, bẹ̃ni emi kì yio ṣãnu fun ọ.

12. Idámẹta rẹ yio kú nipa ajakalẹ arùn, nwọn o si run li ãrin rẹ nipa iyàn, idámẹta yio si ṣubu nipa idà yi ọ ka kiri, emi o si tú idamẹta ká si gbogbo ẹfũfù, emi o si yọ idà tẹle wọn.

13. Bayi ni ibinu mi o ṣẹ, emi o si mu ibinu mi duro lori wọn, inu mi yio si tutù: nwọn o si mọ̀ pe emi Oluwa ti sọ ọ ninu itara mi, nigbati mo ba pari ibinu mi ninu wọn.

14. Emi o si fi ọ ṣòfo, emi o si sọ ọ di ẹ̀gan lãrin awọn orilẹ-ède ti o yi ọ ka kiri, li oju gbogbo awọn ti nkọja.

Esek 5