Esek 44:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si mu mi pada lọna ẹnu-ọ̀na ibi mimọ́ ti ode ti o kọju si ila-õrun; o si tì.

2. Oluwa si wi fun mi pe; Ẹnu-ọ̀na yi yio wà ni titì, a kì yio ṣi i, ẹnikan kì yio si gbà a wọ inu rẹ̀; nitori Oluwa, Ọlọrun Israeli, ti gbà a wọ inu rẹ̀, yio si wà ni titì.

3. Fun ọmọ-alade ni; ọmọ-alade, on ni yio joko ninu rẹ̀ lati jẹ akara niwaju Oluwa; yio wọ̀ ọ lati ọ̀na iloro ẹnu-ọ̀na na, yio si jade lati ọ̀na rẹ̀ na lọ.

4. O si mu mi wá ọ̀na ẹnu-ọ̀na ariwa siwaju ile na; mo si wò, si kiyesi i, ogo Oluwa kun ile Oluwa: mo si doju mi bolẹ.

5. Oluwa si wi fun mi pe, Ọmọ enia, fi iyè rẹ si i, si fi oju rẹ wò, si fi eti rẹ gbọ́ ohun gbogbo ti emi ti sọ fun ọ niti gbogbo aṣẹ ile Oluwa, ati ti gbogbo ofin rẹ̀; si fi iyè rẹ si iwọ̀nu ile nì, pẹlu gbogbo ijadelọ ibi-mimọ́ na.

6. Iwọ o si wi fun awọn ọlọ̀tẹ, ani fun ile Israeli, pe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; ki gbogbo ohun-irira nyin to fun nyin, ile Israeli,

7. Niti pe ẹ mu ọmọ-ajèji, alaikọla aiya, ati alaikọla ara wa, lati wà ni ibi-mimọ́ mi, lati sọ ọ di alailọ̀wọ, ani ile mi, nigbati ẹ rú akara mi, ọ̀ra ati ẹjẹ, nwọn si bà majẹmu mi jẹ nipa gbogbo ohun-irira nyin.

8. Ẹ kò si pa ibi-iṣọ́ ohun-mimọ́ mi mọ́: ṣugbọn ẹ ti yàn oluṣọ́ ibi-iṣọ́ inu ibi-mimọ́ mi fun ara nyin.

9. Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi: Gbogbo ọmọ àjeji, alaikọla aiya, tabi alaikọla ara kì yio wọ̀ inu ibi mimọ́ mi, ninu gbogbo ọmọ àjeji ti o wà lãrin awọn ọmọ Israeli.

10. Ṣugbọn awọn Lefi ti o ti lọ jina kuro lọdọ mi, ni ìṣina Israeli, ti nwọn ṣìna kuro lọdọ mi lẹhin oriṣa wọn: yio si rù aiṣedede wọn.

11. Nwọn o si jẹ iranṣẹ ni ibi mimọ́ mi, oluṣọ́ ẹnu-ọ̀na ile, nwọn o si ma ṣe iranṣẹ ni ile: awọn ni yio pa ọrẹ-ẹbọ sisun ati ẹbọ fun awọn enia, nwọn o si duro niwaju wọn lati ṣe iranṣẹ fun wọn.

Esek 44