Esek 39:16-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Orukọ ilu na pẹlu yio si jẹ Hamona. Bayi ni nwọn o si sọ ilẹ na di mimọ́.

17. Ati iwọ, ọmọ enia, bayi li Oluwa Ọlọrun wi: Sọ fun olukuluku ẹiyẹ abiyẹ́, ati fun olukuluku ẹranko igbẹ, pe, Ẹ ko ara nyin jọ, ki ẹ si wá: ẹ gbá ara nyin jọ ni ihà gbogbo si ẹbọ mi ti emi rú fun nyin, ani irubọ nla lori oke giga Israeli, ki ẹnyin ba le jẹ ẹran, ki ẹ si mu ẹjẹ.

18. Ẹnyin o jẹ ẹran-ara awọn alagbara, ẹnyin o si mu ẹjẹ awọn ọmọ-alade aiye, ti agbò, ti ọdọ agutan, ati ti obukọ, ti akọ malũ, gbogbo wọn abọpa Baṣani.

19. Ẹ o si jẹ ọra li ajẹyo, ẹ o si mu ẹjẹ li amupara, lati inu ẹbọ mi ti mo ti rú fun nyin.

20. Bayi li a o fi ẹṣin ati ẹlẹṣin bọ́ nyin yo lori tabili mi, pẹlu awọn alagbara, ati gbogbo awọn ologun, ni Oluwa Ọlọrun wi.

21. Emi o si gbe ogo mi kalẹ lãrin awọn keferi, gbogbo awọn keferi yio si ri idajọ mi ti mo ti ṣe, ati ọwọ́ mi ti mo ti fi le wọn.

22. Ile Israeli yio si mọ̀ pe, Emi li Oluwa Ọlọrun wọn lati ọjọ na lọ titi.

23. Awọn keferi yio si mọ̀ pe Israeli lọ si igbekùn nitori aiṣedẽde wọn: nitoriti nwọn ti ṣọ̀tẹ si mi, nitorina ni mo ṣe fi oju mi pamọ kuro lọdọ wọn, ti mo si fi wọn le awọn ọta wọn lọwọ: gbogbo wọn si ti ipa idà ṣubu.

24. Gẹgẹ bi aimọ́ wọn, ati gẹgẹ bi irekọja wọn ni mo ṣe si wọn, mo si fi oju mi pamọ́ kuro lọdọ wọn.

25. Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nisisiyi li emi o mu igbèkun Jakobu padà bọ̀, emi o si ṣãnu fun gbogbo ile Israeli, emi o si jowu nitori orukọ mi mimọ́:

Esek 39