15. Awọn èro ti nlà ilẹ na kọja, nigbati ẹnikan ba ri egungun enia kan, yio sàmi kan si ẹba rẹ̀, titi awọn asinku yio fi sin i si afonifoji Hamon-gogu.
16. Orukọ ilu na pẹlu yio si jẹ Hamona. Bayi ni nwọn o si sọ ilẹ na di mimọ́.
17. Ati iwọ, ọmọ enia, bayi li Oluwa Ọlọrun wi: Sọ fun olukuluku ẹiyẹ abiyẹ́, ati fun olukuluku ẹranko igbẹ, pe, Ẹ ko ara nyin jọ, ki ẹ si wá: ẹ gbá ara nyin jọ ni ihà gbogbo si ẹbọ mi ti emi rú fun nyin, ani irubọ nla lori oke giga Israeli, ki ẹnyin ba le jẹ ẹran, ki ẹ si mu ẹjẹ.
18. Ẹnyin o jẹ ẹran-ara awọn alagbara, ẹnyin o si mu ẹjẹ awọn ọmọ-alade aiye, ti agbò, ti ọdọ agutan, ati ti obukọ, ti akọ malũ, gbogbo wọn abọpa Baṣani.
19. Ẹ o si jẹ ọra li ajẹyo, ẹ o si mu ẹjẹ li amupara, lati inu ẹbọ mi ti mo ti rú fun nyin.
20. Bayi li a o fi ẹṣin ati ẹlẹṣin bọ́ nyin yo lori tabili mi, pẹlu awọn alagbara, ati gbogbo awọn ologun, ni Oluwa Ọlọrun wi.
21. Emi o si gbe ogo mi kalẹ lãrin awọn keferi, gbogbo awọn keferi yio si ri idajọ mi ti mo ti ṣe, ati ọwọ́ mi ti mo ti fi le wọn.
22. Ile Israeli yio si mọ̀ pe, Emi li Oluwa Ọlọrun wọn lati ọjọ na lọ titi.