1. Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,
2. Ọmọ enia, kọ oju rẹ si oke Seiri, ki o si sọtẹlẹ si i.
3. Ki o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, Kiyesi i, iwọ oke Seiri, emi dojukọ ọ, emi o nà ọwọ́ mi si ọ, emi o si sọ ọ di ahoro patapata.
4. Emi o sọ awọn ilu rẹ di ahoro, iwọ o si di ahoro, iwọ o si mọ̀ pe, emi li Oluwa.
5. Nitori ti iwọ ti ni irira lailai, iwọ si ti fi awọn ọmọ Israeli le idà lọwọ́, li akoko idãmu wọn, li akoko ti aiṣedẽde wọn de opin.
6. Nitorina, bi emi ti wà, ni Oluwa Ọlọrun wi, emi o pèse rẹ silẹ fun ẹ̀jẹ, ẹ̀jẹ yio si lepa rẹ: bi iwọ kò ti korira ẹ̀jẹ nì, ẹ̀jẹ yio lepa rẹ.