Esek 31:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si ṣe li ọdun kọkanla, li oṣù kẹta, li ọjọ ekini oṣù, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá, wipe,

2. Ọmọ enia, sọ fun Farao ọba Egipti, ati fun ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀ pe, Tani iwọ jọ ni titobi rẹ?

3. Kiyesi i, awọn ara Assiria ni igi kedari ni Lebanoni ti o li ẹ̀ka daradara, ti o si ṣiji boni, ti o si ga, ṣonṣo ori rẹ̀ si wà lãrin awọn ẹ̀ka bibò.

4. Omi sọ ọ di nla, ibú gbé e ga soke, o fi awọn odò nla rẹ̀ yi oko rẹ̀ ka, o si rán awọn odo kékèké rẹ̀ si gbogbo igbẹ́.

5. Nitorina a gbe giga rẹ̀ soke jù gbogbo igi igbẹ́ lọ, ẹ̀ka rẹ̀ si di pupọ̀, awọn ẹ̀ka rẹ̀ si di gigùn nitori ọ̀pọlọpọ omi, nigbati o yọ wọn jade.

6. Gbogbo ẹiyẹ oju ọrun kọ́ itẹ́ wọn ninu ẹ̀ka rẹ̀, ati labẹ ẹ̀ka rẹ̀ ni gbogbo ẹranko igbẹ́ bi ọmọ wọn si, ati labẹ ojiji rẹ̀ ni gbogbo awọn orilẹ-ède nla ngbe.

7. Bayi li o ni ẹwà ninu titobi rẹ̀, ninu gigùn ẹ̀ka rẹ̀: nitori ti egbò rẹ̀ wà li ẹbá omi nla.

8. Awọn igi kedari inu ọgbà Ọlọrun kò le bò o mọlẹ: awọn igi firi kò dabi ẹ̀ka rẹ̀, awọn igi kẹsnuti kò si dabi ẹ̀ka rẹ̀; bẹ̃ni kò si igikigi ninu ọgbà Ọlọrun ti o dabi rẹ̀ li ẹwà rẹ̀.

9. Emi ti ṣe e ni ẹwà nipa ọ̀pọlọpọ ẹ̀ka rẹ̀: tobẹ̃ ti gbogbo igi Edeni, ti o wà ninu ọgbà Ọlọrun, ṣe ilara rẹ̀.

Esek 31