Gbogbo ẹiyẹ oju ọrun kọ́ itẹ́ wọn ninu ẹ̀ka rẹ̀, ati labẹ ẹ̀ka rẹ̀ ni gbogbo ẹranko igbẹ́ bi ọmọ wọn si, ati labẹ ojiji rẹ̀ ni gbogbo awọn orilẹ-ède nla ngbe.