Esek 27:29-34 Yorùbá Bibeli (YCE)

29. Gbogbo awọn alajẹ̀, awọn atukọ̀, ati awọn atọ́kọ̀ okun yio sọkalẹ kuro ninu ọkọ̀ wọn, nwọn o duro lori ilẹ.

30. Nwọn o si jẹ ki a gbọ́ ohùn wọn si ọ, nwọn o si kigbe kikoro, nwọn o si kù ekuru sori ara wọn, nwọn o si yi ara wọn ninu ẽru:

31. Nwọn o si fari wọn patapata fun ọ, nwọn o si fi aṣọ-àpo di ara wọn, nwọn o si sọkun fun ọ ni ikorò aiya, pẹlu ohùnrére ẹkun kikorò.

32. Ati ninu arò wọn ni nwọn o si pohùnrére ẹkún fun ọ, nwọn o si pohùnrére ẹkún sori rẹ, wipe, Ta li o dabi Tire, eyiti a parun li ãrin okun?

33. Nigbati ọjà-tità rẹ ti okun jade wá, iwọ tẹ́ orilẹ-ède pupọ lọrun; iwọ fi ọ̀pọlọpọ ọrọ̀ rẹ, ati ọjà rẹ, sọ awọn ọba aiye di ọlọrọ̀.

34. Nisisiyi ti okun fọ́ ọ bajẹ̀ ninu ibú omi, nitorina òwo rẹ, ati gbogbo ẹgbẹ́ rẹ li ãrin rẹ, li o ṣubu.

Esek 27