Esek 23:23-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

23. Awọn ara Babiloni, ati gbogbo awọn ara Kaldea, Pekodu, ati Ṣoa, ati Koa, ati gbogbo awọn ara Assiria pẹlu wọn: gbogbo wọn jẹ ọmọkunrin ti o wunni, balogun ati awọn olori, awọn ọkunrin ti o li okiki, gbogbo wọn li o ngun ẹṣin.

24. Nwọn o si wá fi kẹkẹ́ ogun, kẹkẹ́ ẹrù, ati kekẹ́ kekeke doju kọ ọ, ati pẹlu ìgbajọ ọ̀pọ enia, awọn ti yio doju asà, ati apata, ati akoro kọ ọ niha gbogbo: emi o si gbe idajọ kalẹ niwaju wọn, nwọn o si da ọ lẹjọ gẹgẹ bi idajọ wọn.

25. Emi o si doju owu mi kọ ọ, nwọn o si fi irúnu ba ọ lò: nwọn o fá imu rẹ ati eti rẹ; ati awọn ti o kù ninu rẹ yio ti ọwọ́ idà ṣubu: nwọn o mu awọn ọmọ rẹ ọkunrin, ati awọn ọmọ rẹ obinrin lọ, ati awọn ti o kù ninu rẹ, li a o fi iná run.

26. Nwọn o si bọ aṣọ rẹ, nwọn o si mu ohun ọṣọ daradara rẹ lọ.

27. Bayi li emi o jẹ ki ifẹkufẹ rẹ mọ kuro lọdọ rẹ, ati panṣaga rẹ ti o mu ti ilẹ Egipti wá; tobẹ̃, ti iwọ kì yio gboju rẹ soke si wọn, bẹ̃ni iwọ kì yio si ranti Egipti mọ.

28. Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi o fi ọ le awọn ti iwọ korira lọwọ, li ọwọ́ awọn ẹniti ọkàn rẹ ṣi:

29. Nwọn o si ba ọ lo ilo irira, nwọn o si ko gbogbo iṣẹ rẹ lọ, nwọn o si fi ọ silẹ ni ihoho ati ni goloto: ati ihoho panṣaga rẹ li a o tu silẹ, ti ifẹkufẹ rẹ, ati panṣaga rẹ.

30. Emi o ṣe gbogbo nkan wọnyi si ọ, nitori pe iwọ ti bá awọn keferi ṣe agbere lọ, ati pe iwọ ti fi oriṣa wọn bà ara rẹ jẹ́.

31. Iwọ ti rìn li ọ̀na ẹ̀gbọn rẹ, nitorina li emi o fi ago rẹ̀ le ọ lọwọ.

Esek 23