Emi o si doju owu mi kọ ọ, nwọn o si fi irúnu ba ọ lò: nwọn o fá imu rẹ ati eti rẹ; ati awọn ti o kù ninu rẹ yio ti ọwọ́ idà ṣubu: nwọn o mu awọn ọmọ rẹ ọkunrin, ati awọn ọmọ rẹ obinrin lọ, ati awọn ti o kù ninu rẹ, li a o fi iná run.