8. Iwọ ti gan awọn ohun mimọ́ mi, o si ti sọ ọjọ isimi mi di ailọ̀wọ.
9. Ninu rẹ ni awọn ọkunrin ti o nṣe ofófo lati ta ẹjẹ silẹ wà: ninu rẹ ni nwọn si jẹun lori awọn oke: lãrin rẹ ni nwọn huwà ifẹkufẹ.
10. Ninu rẹ ni nwọn ti tu ihòho baba wọn: ninu rẹ ni nwọn ti tẹ́ obinrin ti a yà sapakan nitori aimọ́ rẹ̀ logo.
11. Ẹnikan si ti ṣe ohun irira pẹlu aya aladugbo rẹ̀: ẹlomiran si ti fi ifẹkufẹ bà aya-ọmọ rẹ̀ jẹ́; ẹlomiran ninu rẹ si ti tẹ́ arabinrin rẹ̀ logo, ọmọ baba rẹ̀.
12. Ninu rẹ ni nwọn ti gba ẹbùn lati ta ẹjẹ silẹ: iwọ ti gba ẹdá ati elé, o si ti fi iwọra jère lara awọn aladugbo rẹ, nipa ilọni lọwọ-gbà; o si ti gbagbe mi, ni Oluwa, Ọlọrun wi.
13. Kiyesi i, nitorina, mo ti fi ọwọ́ lu ọwọ̀ pọ̀ si ère aiṣõtọ rẹ ti o ti jẹ, ati si ẹjẹ rẹ ti o ti wà lãrin rẹ.
14. Ọkàn rẹ le gbà a, tabi ọwọ́ rẹ lè le, li ọjọ ti emi o ba ọ ṣe? emi Oluwa li o ti sọ ọ, emi o sì ṣe e.
15. Emi o fọ́n ọ ká sãrin awọn keferi, emi o si tú ọ ká si orilẹ-ède gbogbo, emi o si run ẽri rẹ kuro lara rẹ.
16. A o si sọ ọ di aìlọwọ ninu ara rẹ loju awọn keferi, iwọ o si mọ̀ pe emi li Oluwa.
17. Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,
18. Ọmọ enia, ile Israeli di idarọ si mi: gbogbo wọn jẹ idẹ, ati tánganran, ati irin, ati ojé, lãrin ileru; ani nwọn jẹ idarọ fadaka.
19. Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitori ti gbogbo nyin di idarọ, kiyesi i, nitorina emi o ko nyin jọ si ãrin Jerusalemu.
20. Gẹgẹ bi nwọn ti ima ko fadaka, ati idẹ, ati irin, ati ojé, ati tánganran jọ si ãrin ileru, lati fin iná si i, ki a lè yọ́ ọ, bẹ̃ni emi o kó nyin ni ibinu mi, ati irúnu mi, emi o si fi nyin sibẹ emi o yọ́ nyin.
21. Nitotọ, emi o ko nyin jọ, emi o si fin iná ibinu mi si nyin lara, ẹ o si di yiyọ́ lãrin rẹ̀.
22. Bi a ti iyọ́ fadaka lãrin ileru, bẹ̃li a o yọ́ nyin lãrin rẹ̀; ẹnyin o si mọ̀ pe emi Oluwa li o ti dà irúnu mi si nyin lori.
23. Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,
24. Ọmọ enia, sọ fun u, Iwọ ni ilẹ ti a kò gbá mọ́, ti a kò si rọ̀jo si i lori lọjọ ibinu.
25. Ìditẹ awọn wolĩ rẹ̀ wà lãrin rẹ̀, bi kiniun ti nke ramuramu ti nṣọdẹ; nwọn ti jẹ ọkàn run, nwọn ti kó ohun iṣura ati ohun iyebiye; nwọn ti sọ ọ̀pọlọpọ di opó fun u lãrin rẹ̀.
26. Awọn alufa rẹ̀ ti rú ofin mi, nwọn si fi sọ ohun mimọ́ mi di àilọwọ: nwọn kò fi ìyatọ sãrin ohun mimọ́ ati àilọwọ, bẹ̃ni nwọn kò fi ìyatọ hàn lãrin ohun aimọ́, ati mimọ́, nwọn si ti fi oju wọn pamọ kuro li ọjọ isimi mi, mo si di ẹmi àilọwọ lãrin wọn.