Esek 21:20-32 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. Yàn ọ̀na kan, ki idà na le wá si Rabba ti awọn ara Ammoni, ati si Juda ni Jerusalemu ti o li odi.

21. Nitori ọba Babiloni duro ni iyàna, lori ọ̀na meji, lati ma lo afọṣẹ: o mì ọfà rẹ̀, o da òriṣa, o wo ẹ̀dọ.

22. Li ọwọ́ ọtún rẹ̀ ni afọṣẹ Jerusalemu wà, lati yan õlù, lati ya ẹnu rẹ̀ ni pipa, lati gbohùn soke pẹlu ariwo, lati yan õlù si bode, lati mọ odi, ati lati kọ ile iṣọ́.

23. Afọ̀ṣẹ na yio si dabi eké fun wọn, loju awọn ti o ti bura fun wọn: ṣugbọn on o mu aiṣedẽde wá si iranti, ki a ba le mu wọn.

24. Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitoripe ẹnyin jẹ ki a ranti aiṣedẽde nyin, niti pe a ri irekọja nyin, tobẹ̃ ti ẹ̀ṣẹ nyin hàn, ni gbogbo iṣe nyin: nitoripe ẹnyin wá si iranti, ọwọ́ li a o fi mu nyin.

25. Ati iwọ, alailọ̀wọ ẹni-buburu ọmọ-alade Israeli, ẹniti ọjọ rẹ̀ de, nigba aiṣedẽde ikẹhìn.

26. Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Mu fila ọba kuro, si ṣi ade kuro; eyi kò ni jẹ ọkanna: gbe ẹniti o rẹlẹ ga, si rẹ̀ ẹniti o ga silẹ.

27. Emi o bì ṣubu, emi o bì ṣubu, emi o bì i subu, kì yio si si mọ, titi igbati ẹniti o ni i ba de; emi o si fi fun u.

28. Ati iwọ, ọmọ enia, sọtẹlẹ, si wipe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi niti awọn ara Ammoni, ati niti ẹgàn wọn; ani ki iwọ wipe, Idà na, idà na ti a fà yọ, a ti dán a fun pipa, lati parun lati kọ màna.

29. Nigbati nwọn ri ohun asan si ọ, nigbati nwọn fọ̀ àfọṣẹ eke si ọ, lati mu ọ wá si ọrùn awọn ti a pa, ti ẹni-buburu, ẹniti ọjọ rẹ̀ de, nigbati aiṣedẽde pin.

30. Tun mu ki o pada sinu àkọ rẹ̀! Emi o ṣe idajọ rẹ nibi ti a gbe ṣe ẹdá rẹ, ni ilẹ ibi rẹ.

31. Emi o dà ibinujẹ mi le ọ lori, ninu iná irúnu mi li emi o fẹ si ọ, emi o si fi ọ le awọn eniakenia lọwọ, ti nwọn ni ọgbọn lati parun.

32. Iwọ o jẹ́ igi fun iná; ẹjẹ rẹ yio wà lãrin ilẹ na; a kì yio ranti rẹ mọ: nitori emi Oluwa li o ti wi i.

Esek 21