Esek 21:14-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Nitorina, iwọ ọmọ enia, sọtẹlẹ, si fi ọwọ́ lu ọwọ́ pọ̀, si jẹ ki idà ki o ṣẹ́po nigba kẹta, idà awọn ti a pa: idà awọn enia nla ti a pa ni, ti o wọ inu yara ikọ̀kọ wọn lọ.

15. Mo ti nà ṣonṣo idà si gbogbo bode wọn: ki aiya wọn le dakú, ati ki ahoro wọn le di pupọ: ã! a ti ṣe e dán, a ti pọ́n ọ mú silẹ fun pipa.

16. Iwọ gba ọ̀na kan tabi ọ̀na keji lọ, si apa ọtún tabi si òsi, nibikibi ti iwọ dojukọ.

17. Emi o si fi ọwọ́ lu ọwọ́ pọ̀, emi o si jẹ ki irúnu mi ki o simi: emi Oluwa li o ti wi bẹ̃.

18. Ọ̀rọ Oluwa tun tọ̀ mi wá, wipe,

19. Iwọ pẹlu, ọmọ enia, yan ọ̀na meji fun ara rẹ, ki idà ọba Babiloni ki o le wá: awọn mejeji yio jade lati ilẹ kanna wá: si yan ibi kan, yàn a ni ikorita ti o lọ si ilu-nla.

20. Yàn ọ̀na kan, ki idà na le wá si Rabba ti awọn ara Ammoni, ati si Juda ni Jerusalemu ti o li odi.

21. Nitori ọba Babiloni duro ni iyàna, lori ọ̀na meji, lati ma lo afọṣẹ: o mì ọfà rẹ̀, o da òriṣa, o wo ẹ̀dọ.

22. Li ọwọ́ ọtún rẹ̀ ni afọṣẹ Jerusalemu wà, lati yan õlù, lati ya ẹnu rẹ̀ ni pipa, lati gbohùn soke pẹlu ariwo, lati yan õlù si bode, lati mọ odi, ati lati kọ ile iṣọ́.

23. Afọ̀ṣẹ na yio si dabi eké fun wọn, loju awọn ti o ti bura fun wọn: ṣugbọn on o mu aiṣedẽde wá si iranti, ki a ba le mu wọn.

24. Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitoripe ẹnyin jẹ ki a ranti aiṣedẽde nyin, niti pe a ri irekọja nyin, tobẹ̃ ti ẹ̀ṣẹ nyin hàn, ni gbogbo iṣe nyin: nitoripe ẹnyin wá si iranti, ọwọ́ li a o fi mu nyin.

25. Ati iwọ, alailọ̀wọ ẹni-buburu ọmọ-alade Israeli, ẹniti ọjọ rẹ̀ de, nigba aiṣedẽde ikẹhìn.

26. Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Mu fila ọba kuro, si ṣi ade kuro; eyi kò ni jẹ ọkanna: gbe ẹniti o rẹlẹ ga, si rẹ̀ ẹniti o ga silẹ.

Esek 21