Esek 18:14-30 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Si kiye si i, bi o ba bi ọmọkunrin ti o ri gbogbo ẹ̀ṣẹ baba rẹ̀ ti o ti ṣe, ti o si bẹ̀ru, ti kò si ṣe iru rẹ̀,

15. Ti kò si jẹun lori oke, ti kò gbe oju rẹ̀ soke si oriṣa ile Israeli, ti kò ba obinrin aladugbo rẹ̀ jẹ,

16. Ti kò ni ẹnikan lara, ti kò dá ohun ògo duro, ti kò fi agbara koni, ṣugbọn ti o ti fi onjẹ rẹ̀ fun ẹniti ebi npa, ti o si ti fi ẹ̀wu bo ẹni-ihoho,

17. Ti o ti mu ọwọ́ rẹ̀ kuro lara ẹni-inilara, ti kò ti gba ẹdá tabi elé ti o ti mu idajọ mi ṣẹ, ti o ti rìn ninu aṣẹ mi; on kì yio kú nitori aiṣedẽde baba rẹ̀, yiyè ni yio yè.

18. Bi o ṣe ti baba rẹ̀, nitoripe o fi ikà ninilara, ti o fi agbara ko arakunrin rẹ̀; ti o ṣe eyiti kò dara lãrin enia rẹ̀, kiye si i, on o tilẹ kú ninu aiṣedẽde rẹ̀.

19. Ṣugbọn ẹnyin wipe, Ẽṣe? ọmọ kò ha ru aiṣedẽde baba? Nigbati ọmọ ti ṣe eyiti o tọ́ ati eyiti o yẹ, ti o si ti pa gbogbo aṣẹ mi mọ, ti o si ti ṣe wọn, yiyè ni yio yè.

20. Ọkàn ti o ba ṣẹ̀, on o kú. Ọmọ kì yio rù aiṣedẽde baba, bẹ̃ni baba kì yio rù aiṣedẽde ọmọ: ododo olododo yio wà lori rẹ̀, ìwa buburu enia buburu yio si wà lori rẹ̀.

21. Ṣugbọn bi enia buburu yio ba yipada kuro ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ti da, ti o si pa gbogbo aṣẹ mi mọ, ti o si ṣe eyi ti o tọ́, ati eyiti o yẹ, yiyè ni yio yè, on kì yio kú.

22. Gbogbo irekọja rẹ̀ ti o ti ṣe, a kì yio ranti wọn si i: ninu ododo rẹ̀ ti o ti ṣe ni on o yè.

23. Emi ha ni inu-didùn rara pe ki enia buburu ki o kú? ni Oluwa Ọlọrun wi: kò ṣepe ki o yipada kuro ninu ọ̀na rẹ̀, ki o si yè?

24. Ṣugbọn nigbati olododo ba yipada kuro ninu ododo rẹ̀, ti o si huwà aiṣedede, ti o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo irira ti enia buburu nṣe, on o ha yè? gbogbo ododo rẹ̀ ti o ti ṣe ni a kì yio ranti: ninu irekọja rẹ̀ ti o ti ṣe, ati ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ti da, ninu wọn ni yio kú.

25. Ṣugbọn ẹnyin wipe, ọ̀na Oluwa kò gún. Gbọ́ nisisiyi, iwọ ile Israeli; ọ̀na mi kò ha gún? ọ̀na ti nyin kọ́ kò gún?

26. Nigbati olododo kan ba yipada kuro ninu ododo rẹ̀, ti o si huwà aiṣedẽde, ti o si kú ninu wọn; nitori aiṣedẽde rẹ̀ ti o ti ṣe ni yio kú.

27. Ẹwẹ, nigbati enia buburu ba yipada kuro ninu ìwa buburu rẹ̀ ti o ti ṣe, ti o si ṣe eyiti o tọ́, ati eyiti o yẹ, on o gba ọkàn rẹ̀ là lãye.

28. Nitoripe o bẹ̀ru o si yipada kuro ninu gbogbo irekọja rẹ̀ ti o ti ṣe, yiyè ni yio yè, on kì yio kú.

29. Ṣugbọn ile Israeli wipe, Ọ̀na Oluwa kò gún. Ile Israeli, ọ̀na mi kò ha gún? ọ̀na ti nyin kọ́ kò gún?

30. Nitorina emi o dá nyin lẹjọ, ile Israeli, olukuluku gẹgẹ bi ọ̀na rẹ̀, ni Oluwa Ọlọrun wi. Ẹ yipada, ki ẹ si yi kuro ninu gbogbo irekọja nyin; bẹ̃ni aiṣedẽde kì yio jẹ iparun nyin.

Esek 18