Eks 9:21-35 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. Ẹniti kò si kà ọ̀rọ OLUWA si, jọwọ awọn iranṣẹ rẹ̀ ati awọn ẹran-ọ̀sin rẹ̀ si oko.

22. OLUWA si sọ fun Mose pe, Nà ọwọ́ rẹ si oke ọrun, ki yinyin ki o le bọ́ si gbogbo ilẹ Egipti, sara enia, ati sara ẹranko, ati sara eweko igbẹ́ gbogbo, já gbogbo ilẹ Egipti.

23. Mose si nà ọpá rẹ̀ si ọrun: OLUWA si rán ãra ati yinyin, iná na si njó lori ilẹ; OLUWA si rọ̀ yinyin sori ilẹ Egipti.

24. Yinyin si bọ́, iná si dàpọ mọ́ yinyin na, o papọ̀ju, irú rẹ̀ kò si ri ni gbogbo ilẹ Egipti lati ìgba ti o ti di orilẹ-ède.

25. Yinyin na si lù ohun gbogbo ti o wà ninu oko bolẹ, ati enia ati ẹranko, já gbogbo ilẹ Egipti; yinyin na si lù gbogbo eweko bolẹ, o si fà gbogbo igi igbẹ́ ya.

26. Ni kìki ilẹ Goṣeni, nibiti awọn ọmọ Israeli gbé wà, ni yinyin kò si.

27. Farao si ranṣẹ, o si pè Mose ati Aaroni, o si wi fun wọn pe, Emi ṣẹ̀ nigbayi: OLUWA li olododo, ẹni buburu si li emi ati awọn enia mi.

28. Ẹ bẹ̀ OLUWA (o sa to) ki ãra nla ati yinyin wọnyi ki o máṣe si mọ́; emi o si jẹ ki ẹ ma lọ; ẹ ki yio si duro mọ́.

29. Mose si wi fun u pe, Bi mo ba ti jade ni ilu, emi o tẹ́ ọwọ́ mi si OLUWA; ãra yio si dá, bẹ̃ni yinyin ki yio si mọ́; ki iwọ ki o le mọ̀ pe ti OLUWA li aiye.

30. Ṣugbọn bi o ṣe tirẹ ni ati ti awọn iranṣẹ rẹ, emi mọ̀ pe sibẹ, ẹnyin kò ti ibẹ̀ru OLUWA Ọlọrun.

31. A si lù ọgbọ́ ati ọkà barle bolẹ; nitori ọkà barle wà ni ipẹ́, ọgbọ́ si rudi.

32. Ṣugbọn alikama ati ọkà (rie) li a kò lù bolẹ: nitoriti nwọn kò ti idàgba.

33. Mose si jade kuro lọdọ Farao sẹhin ilu, o si tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ si OLUWA; ãra ati yinyin si dá, bẹ̃li òjo kò si rọ̀ si ilẹ̀ mọ́.

34. Nigbati Farao ri pe, òjo ati yinyin ati ãra dá, o ṣẹ̀ si i, o si sé àiya rẹ̀ le, on ati awọn iranṣẹ rẹ̀.

35. Àiya Farao si le, bẹ̃ni kò si jẹ ki awọn ọmọ Israeli ki o lọ; bi OLUWA ti wi lati ọwọ́ Mose.

Eks 9