Mose si wi fun u pe, Bi mo ba ti jade ni ilu, emi o tẹ́ ọwọ́ mi si OLUWA; ãra yio si dá, bẹ̃ni yinyin ki yio si mọ́; ki iwọ ki o le mọ̀ pe ti OLUWA li aiye.