Eks 5:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. LẸHIN eyinì ni Mose ati Aaroni wọle, nwọn si wi fun Farao pe, Bayi li OLUWA, Ọlọrun Israeli wi, Jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, ki nwọn ki o le ṣe ajọ fun mi ni ijù.

2. Farao si wipe, Tali OLUWA, ti emi o fi gbà ohùn rẹ̀ gbọ́ lati jẹ ki Israeli ki o lọ? Emi kò mọ̀ OLUWA na, bẹ̃li emi ki yio jẹ ki Israeli ki o lọ.

3. Nwọn si wipe, Ọlọrun awọn Heberu li o pade wa: awa bẹ̀ ọ, jẹ ki a lọ ni ìrin ijọ́ mẹta si ijù, ki a si rubọ si OLUWA Ọlọrun wa; ki o má ba fi ajakalẹ-àrun tabi idà kọlù wa.

4. Ọba Egipti si wi fun wọn pe, Mose ati Aaroni, nitori kili ẹnyin ṣe dá awọn enia duro ninu iṣẹ wọn? ẹ lọ si iṣẹ nyin.

5. Farao si wipe, Kiyesi i awọn enia ilẹ yi pọ̀ju nisisiyi, ẹnyin si mu wọn simi kuro ninu iṣẹ wọn.

6. Farao si paṣẹ li ọjọ́ na fun awọn akoniṣiṣẹ awọn enia, ati fun awọn olori wọn wipe,

7. Ẹnyin kò gbọdọ fun awọn enia na ni koriko mọ́ lati ma ṣe briki, bi ìgba atẹhinwá: jẹ ki nwọn ki o ma lọ ṣà koriko fun ara wọn.

8. Ati iye briki ti nwọn ti ima ṣe ni ìgba atẹhinwá, on ni ki ẹnyin bù fun wọn; ẹnyin kò gbọdọ ṣẹ nkan kù kuro nibẹ̀: nitoriti nwọn nṣe imẹlẹ; nitorina ni nwọn ṣe nke wipe, Jẹ ki a lọ rubọ si Ọlorun wa.

9. Ẹ jẹ ki iṣẹ ki o wuwo fun awọn ọkunrin na, ki nwọn ki o le ma ṣe lãlã ninu rẹ̀; ẹ má si ṣe jẹ ki nwọn ki o fiyesi ọ̀rọ eke.

10. Awọn akoniṣiṣẹ enia na si jade, ati awọn olori wọn, nwọn si sọ fun awọn enia na, pe, Bayi ni Farao wipe, Emi ki yio fun nyin ni koriko mọ́.

11. Ẹ lọ, ẹ wá koriko nibiti ẹnyin gbé le ri i: ṣugbọn a ki yio ṣẹ nkan kù ninu iṣẹ nyin.

12. Bẹ̃li awọn enia na si tuka kiri ká gbogbo ilẹ Egipti lati ma ṣà idi koriko ni ipò koriko.

Eks 5