Awọn akoniṣiṣẹ enia na si jade, ati awọn olori wọn, nwọn si sọ fun awọn enia na, pe, Bayi ni Farao wipe, Emi ki yio fun nyin ni koriko mọ́.