12. Apoti nì, ati ọpá rẹ̀, itẹ́-ãnu nì, ati aṣọ-ikele na;
13. Tabili na, ati ọpá rẹ̀, ati ohun-èlo rẹ̀ gbogbo, ati àkara ifihàn nì;
14. Ati ọpà-fitila na fun titanna, ati ohun-elo rẹ̀, ati fitila rẹ̀, pẹlu oróro fun titanna.
15. Ati pẹpẹ turari, ati ọpá rẹ̀, ati oróro itasori, ati turari didùn, ati aṣọ-sisorọ̀ fun ẹnu-ọ̀na, ani atiwọle ẹnu agọ́ na;
16. Ati pẹpẹ ẹbọsisun, ti on ti àwọn oju-àro idẹ rẹ̀, ati ọpá rẹ̀, ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀, agbada na ti on ti ẹsẹ rẹ̀;
17. Aṣọ-isorọ̀ ti agbalá, ọwọ̀n rẹ̀, ati ihò-ìtẹbọ rẹ̀, ati aṣọ-isorọ̀ fun ẹnu-ọ̀na agbalá na;
18. Ekàn agọ́ na, ati ekàn agbalá na, ati okùn wọn;
19. Aṣọ ìsin wọnni, lati sìn ni ibi mimọ́, aṣọ mimọ́ wọnni fun Aaroni alufa, ati aṣọ awọn ọmọ rẹ̀, lati ma fi ṣe iṣẹ alufa.