31. Mose si kọ si wọn; ati Aaroni ati gbogbo awọn ijoye inu ajọ si pada tọ̀ ọ́ wá: Mose si bá wọn sọ̀rọ.
32. Lẹhin eyinì ni gbogbo awọn ọmọ Israeli si sunmọ ọ: o si paṣẹ gbogbo ohun ti OLUWA bá a sọ lori òke Sinai fun wọn.
33. Nigbati Mose si bá wọn sọ̀rọ tán, o fi iboju bò oju rẹ̀.
34. Ṣugbọn nigbati Mose ba lọ si iwaju OLUWA lati bá a sọ̀rọ, a mú iboju na kuro titi o fi jade: a si jade, a si bá awọn ọmọ Israeli sọ̀rọ aṣẹ ti a pa fun u.
35. Awọn ọmọ Israeli si ri oju Mose pe, awọ, oju rẹ̀ ndán: Mose si tun fi iboju bò oju rẹ̀, titi o fi wọle lọ bá a sọ̀rọ.