26. Akọ́so eso ilẹ rẹ ni ki iwọ ki o mú wa si ile OLUWA Ọlọrun rẹ. Iwọ kò gbọdọ bọ̀ ọmọ ewurẹ ninu warà iya rẹ̀.
27. OLUWA si wi fun Mose pe, Iwọ kọwe ọ̀rọ wọnyi: nitori nipa ìmọ ọ̀rọ wọnyi li emi bá iwọ ati Israeli dá majẹmu.
28. On si wà nibẹ̀, lọdọ OLUWA li ogoji ọsán ati ogoji oru: on kò jẹ onjẹ, bẹ̃ni kò mu omi. On si kọwe ọ̀rọ majẹmu na, ofin mẹwa nì, sara walã wọnni.
29. O si ṣe, nigbati Mose sọkalẹ lati ori òke Sinai wá ti on ti walã ẹrí mejeji nì li ọwọ́ Mose, nigbati o sọkalẹ ti ori òke na wá, ti Mose kò mọ̀ pe awọ oju on ndán nitoriti o bá a sọ̀rọ.
30. Nigbati Aaroni ati gbogbo awọn ọmọ Israeli ri Mose, kiyesi i, awọ oju rẹ̀ ndán; nwọn si bẹ̀ru lati sunmọ ọdọ rẹ̀.