10. On si wipe, Kiyesi i, emi dá majẹmu kan: emi o ṣe ohun iyanu, niwaju gbogbo awọn enia rẹ irú eyiti a kò ti iṣe lori ilẹ gbogbo rí, ati ninu gbogbo orilẹ-ède: ati gbogbo enia ninu awọn ti iwọ wà, nwọn o ri iṣẹ OLUWA, nitori ohun ẹ̀ru li emi o fi ọ ṣe.
11. Iwọ kiyesi eyiti emi palaṣẹ fun ọ li oni yi: kiyesi i, emi lé awọn Amori jade niwaju rẹ, ati awọn ara Kenaani, ati awọn ara Hitti, ati awọn ara Perissi, ati awọn ara Hifi, ati awọn ara Jebusi.
12. Ma ṣọ́ ara rẹ ki iwọ ki o má ba bá awọn ara ilẹ na dá majẹmu, nibikibi ti iwọ nlọ, ki o má ba di idẹwò fun ọ lãrin rẹ:
13. Bikoṣepe ki ẹnyin ki o wó pẹpẹ wọn, ki ẹnyin ki o fọ́ ọwọ̀n wọn, ki ẹnyin si wó ere oriṣa wọn lulẹ.
14. Nitoriti ẹnyin kò gbọdọ bọ oriṣa: nitori OLUWA, orukọ ẹniti ijẹ Ojowu, Ọlọrun ojowú li on:
15. Ki iwọ ki o má ba bá awọn ara ilẹ na dá majẹmu, nigbati nwọn ba nṣe àgbere tọ̀ oriṣa wọn, ti nwọn si nrubọ si oriṣa wọn, ti nwọn si pè ọ ti iwọ si lọ jẹ ninu ẹbọ wọn;
16. Ki iwọ ki o má si ṣe fẹ́ ninu awọn ọmọbinrin wọn fun awọn ọmokọnrin rẹ, ki awọn ọmọbinrin wọn ki o má ba ṣe àgbere tọ̀ oriṣa wọn, ki nwọn ki o má ba mu ki awọn ọmọkunrin rẹ ki o ṣe àgbere tọ̀ oriṣa wọn.
17. Iwọ kò gbọdọ dà ere oriṣakoriṣa kan fun ara rẹ.
18. Ajọ aiwukàra ni ki iwọ ki o ma pamọ́. Ijọ́ meje ni iwọ o jẹ àkara alaiwu, bi mo ti paṣẹ fun ọ, ni ìgba oṣù Abibu: nitoripe li oṣù Abibu ni iwọ jade kuro ni Egipti.
19. Gbogbo akọ́bi ni ti emi; ati akọ ninu gbogbo ohunọ̀sin rẹ; akọ́bi ti malu, ati ti agutan.
20. Ṣugbọn akọ́bi kẹtẹkẹtẹ ni ki iwọ ki o fi ọdọ-agutan rapada: bi iwọ kò ba si rà a pada, njẹ ki iwọ ki o ṣẹ́ ẹ li ọrùn. Gbogbo akọ́bi ninu awọn ọmọkunrin rẹ ni ki iwọ ki o rapada. Kò si sí ẹnikan ti yio farahàn niwaju mi lọwọ ofo.
21. Ijọ́ mẹfa ni ki iwọ ki o ṣe iṣẹ́, ṣugbọn ni ijọ́ keje ni ki iwọ ki o simi: ni ìgba ifunrugbìn, ati ni ìgba ikore ni ki iwọ ki o simi.
22. Iwọ o si ma kiyesi ajọ ọ̀sẹ, akọ́so eso alikama, ati ajọ ikore li opin ọdún.
23. Li ẹrinmẹta li ọdún kan ni gbogbo awọn ọmọkunrin rẹ yio farahàn niwaju Oluwa, ỌLỌRUN, Ọlọrun Israeli.
24. Nitoriti emi o lé awọn orilẹ-ède nì jade niwaju rẹ, emi o si fẹ̀ ipinlẹ rẹ: bẹ̃li ẹnikẹni ki yio fẹ́ ilẹ̀-iní rẹ, nigbati iwọ o gòke lọ lati pejọ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ li ẹrinmẹta li ọdún kan.