2. Iwọ o si dá aṣọ mimọ́ fun Aaroni arakunrin rẹ fun ogo ati fun ọṣọ́.
3. Iwọ o si sọ fun gbogbo awọn ti o ṣe amoye, awọn ẹniti mo fi ẹmi ọgbọ́n kún, ki nwọn ki o le dá aṣọ Aaroni lati yà a simimọ́, ki o le ma ṣe iṣẹ alufa fun mi.
4. Wọnyi si li aṣọ ti nwọn o dá; igbàiya kan, ati ẹ̀wu-efodi, ati aṣọ igunwà, ati ẹ̀wu-awọtẹlẹ ọlọnà, fila, ati ọjá-amure: nwọn o si dá aṣọ mimọ́ wọnyi fun Aaroni arakunrin rẹ, ati fun awọn ọmọ rẹ̀, ki on ki o le ma ṣe iṣẹ alufa fun mi.
5. Nwọn o si mú wurà, ati aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ.
6. Nwọn o si ṣe ẹ̀wu-efodi ti wurà, ti aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ti ododó, ati ọ̀gbọ olokùn wiwẹ iṣẹ ọlọnà,
7. Yio ní aṣọ ejika meji ti o solù li eti rẹ̀ mejeji; bẹ̃ni ki a so o pọ̀.
8. Ati onirũru-ọnà ọjá rẹ̀, ti o wà lori rẹ̀ yio ri bakanna, gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀; ti wurà, ti aṣọ-alaró, ododó, ati ọ̀gbọ olokùn wiwẹ.
9. Iwọ o si mú okuta oniki meji, iwọ o si fin orukọ awọn ọmọ Israeli sara wọn: