16. Iha mẹrin ọgbọgba ni ki iwọ ki o ṣe e ni iṣẹpo meji; ika kan ni ìna rẹ̀, ika kan si ni ibú rẹ̀.
17. Iwọ o si tò ìto okuta sinu rẹ̀, ẹsẹ̀ okuta mẹrin: ẹsẹ̀ kini, sardiu, topasi, ati smaragdu; eyi li ẹsẹ̀ kini:
18. Ẹsẹ̀ keji, emeraldi, safiru, ati diamondi;
19. Ati ẹsẹ̀ kẹta, ligure, agate, ati ametistu;
20. Ati ẹsẹ̀ kẹrin, berilu, ati oniki, ati jasperi: a o si tò wọn si oju wurà ni didè wọn.