10. Bi enia ba fi kẹtẹkẹtẹ, tabi akọmalu, tabi agutan, tabi ẹrankẹran lé ẹnikeji rẹ̀ lọwọ lati ma sìn; ti o ba si kú, tabi ti o farapa, tabi ti a lé e sọnù, ti ẹnikan kò ri i;
11. Ibura OLUWA yio wà lãrin awọn mejeji, pe, on kò fọwọkàn ẹrù ẹnikeji on; ki on ki o si gbà, on ki yio si san ẹsan.
12. Bi o ba ṣepe a ji i lọwọ rẹ̀, on o san ẹsan fun oluwa rẹ̀.
13. Bi o ba ṣepe a si fà a ya, njẹ ki o mú u wa ṣe ẹrí, on ki yio si san ẹsan eyiti a fàya.
14. Bi enia ba si yá ohun kan lọwọ ẹnikeji rẹ̀, ti o si farapa, tabi ti o kú, ti olohun kò si nibẹ̀, on o san ẹsan nitõtọ.
15. Ṣugbọn bi olohun ba wà nibẹ̀, on ki yio san ẹsan: bi o ba ṣe ohun ti a fi owo gbà lò ni, o dé fun owo igbàlo rẹ̀.
16. Bi ọkunrin kan ba si tàn wundia kan ti a kò ti ifẹ́, ti o si mọ̀ ọ, fifẹ́ ni yio si fẹ́ ẹ li aya rẹ̀.
17. Bi baba rẹ̀ ba kọ̀ jalẹ lati fi i fun u, on o san ojì gẹgẹ bi ifẹ́ wundia.
18. Iwọ kò gbọdọ jẹ ki ajẹ́ ki o wà lãye.
19. Ẹnikẹni ti o ba bá ẹranko dàpọ pipa li a o pa a.
20. Ẹnikẹni ti o ba rubọ si oriṣakoriṣa, bikoṣe si JEHOFA nikanṣoṣo, a o pa a run tútu.
21. Iwọ kò gbọdọ ṣìka si alejò, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ni i lara: nitoripe alejò li ẹnyin ti jẹ́ ni ilẹ Egipti.
22. Ẹnyin kò gbọdọ jẹ opó ni ìya, tabi ọmọ alainibaba.
23. Bi iwọ ba jẹ wọn ni ìyakiya, ti nwọn si kigbe pè mi, emi o gbọ́ igbe wọn nitõtọ.
24. Ibinu mi yio si gboná, emi o si fi idà pa nyin; awọn aya nyin yio si di opó, awọn ọmọ nyin a si di alainibaba.
25. Bi iwọ ba yá ẹnikẹni ninu awọn enia mi li owo ti o ṣe talaka lọdọ rẹ, iwọ ki yio jẹ́ bi agbẹ̀da fun u; bẹ̃ni iwọ ki yio gbẹ̀da lọwọ rẹ̀.