8. Bi on kò ba wù oluwa rẹ̀, ti o ti fẹ́ ẹ fun ara rẹ̀, njẹ ki o jẹ ki a rà a pada, on ki yio lagbara lati tà a fun ajeji enia, o sa ti tàn a jẹ.
9. Bi o ba si fẹ́ ẹ fun ọmọkunrin rẹ̀, ki o ma ṣe si i bi a ti iṣe si ọmọbinrin ẹni.
10. Bi o ba si fẹ́ obinrin miran; onjẹ rẹ̀, aṣọ rẹ̀, ati iṣe ọkọlaya rẹ̀, ki o máṣe yẹ̀.
11. Bi on ki yio ba si ṣe ohun mẹtẹta yi fun u, njẹ ki on ki o jade kuro lọfẹ li aisan owo.
12. Ẹniti o ba lù enia, tobẹ̃ ti o si ku, pipa li a o pa a.
13. Bi o ba ṣepe enia kò ba dèna, ṣugbọn ti o ṣepe Ọlọrun li o fi lé e lọwọ, njẹ emi o yàn ibi fun ọ, nibiti on o gbé salọ si.
14. Ṣugbọn bi enia ba ṣìka si aladugbo rẹ̀, lati fi ẹ̀tan pa a; ki iwọ ki o tilẹ mú u lati ibi pẹpẹ mi lọ, ki o le kú.
15. Ẹniti o ba si lù baba, tabi iya rẹ̀, pipa li a o pa a.
16. Ẹniti o ba si ji enia, ti o si tà a, tabi ti a ri i li ọwọ́ rẹ̀, pipa li a o pa a.
17. Ẹniti o ba si bú baba tabi iya rẹ̀, pipa li a o pa a.
18. Bi awọn ọkunrin ba si jùmọ̀ njà, ti ekini fi okuta lù ekeji, tabi ti o jìn i li ẹsẹ̀, ti on kò si kú ṣugbọn ti o da a bulẹ:
19. Bi o ba si tun dide, ti o ntẹ̀ ọpá rìn kiri ni ita, nigbana li ẹniti o lù u yio to bọ́; kìki gbèse akokò ti o sọnù ni yio san, on o si ṣe ati mu u lara da ṣaṣa.
20. Bi ẹnikan ba si fi ọpá lù ẹrú rẹ̀ ọkunrin tabi obinrin, ti o si kú si i li ọwọ́, a o gbẹsan rẹ̀ nitõtọ.