21. Awọn enia si duro li òkere rére, Mose si sunmọ ibi òkunkun ṣiṣu na nibiti Ọlọrun gbé wà.
22. OLUWA si wi fun Mose pe, Bayi ni ki iwọ ki o wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹnyin ri bi emi ti bá nyin sọ̀rọ lati ọrun wá.
23. Ẹnyin kò gbọdọ ṣe ọlọrun miran pẹlu mi; Ẹnyin kò gbọdọ ṣe ọlọrun fadaka, tabi ọlọrun wurà, fun ara nyin.
24. Pẹpẹ erupẹ ni ki iwọ mọ fun mi, lori rẹ̀ ni ki iwọ ki o ma ru ẹbọ sisun rẹ, ati ẹbọ alafia rẹ, agutan rẹ, ati akọmalu rẹ: ni ibi gbogbo ti mo ba gbé fi iranti orukọ mi si, emi o ma tọ̀ ọ wá, emi o si ma bukún fun ọ.
25. Bi iwọ o ba si mọ pẹpẹ okuta fun mi, iwọ kò gbọdọ fi okuta gbigbẹ́ mọ ọ: nitori bi iwọ ba gbé ohun-ọnà rẹ lé ori rẹ̀, iwọ sọ ọ di aimọ́.
26. Iwọ kò si gbọdọ ba àkasọ gùn ori pẹpẹ mi, ki ìhoho rẹ ki o máṣe hàn lori rẹ̀.