Eks 1:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NJẸ orukọ awọn ọmọ Israeli, ti o wá si Egipti pẹlu Jakobu ni wọnyi; olukuluku pẹlu ile rẹ̀.

2. Reubeni, Simeoni, Lefi, ati Judah;

3. Issakari, Sebuluni, ati Benjamini;

4. Dani ati Naftali, Gadi ati Aṣeri.

5. Ati gbogbo ọkàn ti o ti inu Jakobu jade, o jẹ́ ãdọrin ọkàn: Josefu sa ti wà ni Egipti.

6. Josefu si kú, ati gbogbo awọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo iran na.

7. Awọn ọmọ Israeli si bisi i, nwọn si pọ̀si i gidigidi, nwọn si rẹ̀, nwọn si di alagbara nla jọjọ; ilẹ na si kún fun wọn.

8. Ọba titun miran si wa ijẹ ni Egipti, ti kò mọ́ Josefu.

9. O si wi fun awọn enia rẹ̀ pe, kiye si i, enia awọn ọmọ Israeli npọ̀, nwọn si nlagbara jù wa lọ:

10. Ẹ wá na, ẹ jẹ ki a fi ọgbọ́n ba wọn ṣe; ki nwọn ki o máṣe bisi i, yio si ṣe nigbati ogun kan ba ṣẹ̀, nwọn o dàpọ mọ́ awọn ọtá wa pẹlu, nwọn o ma bá wa jà, nwọn o si jade kuro ni ilẹ yi.

Eks 1