Ẹk. Jer 4:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. BAWO ni wura ṣe di baibai! bawo ni wura didara julọ ṣe pada! okuta ibi-mimọ́ li a tuka ni gbogbo ori ita.

2. Awọn ọmọ iyebiye Sioni, ti o niye lori bi wura didara, bawo li a ṣe kà wọn si bi ikoko amọ̀, iṣẹ ọwọ alamọ̀!

3. Ani ọ̀wawa nfà ọmu jade, nwọn nfi ọmu fun awọn ọmọ wọn: ṣugbọn ọmọbinrin awọn enia mi ti di ìka, gẹgẹ bi abo ògongo li aginju.

4. Ahọn ọmọ-ọmu lẹ̀ mọ oke ẹnu rẹ̀ nitori ongbẹ: awọn ọmọ kekere mbere onjẹ, ẹnikan kò si bu u fun wọn.

5. Awọn ti o ti njẹ ohun didùndidùn nkú lọ ni ita: awọn ti a ti tọ́ ninu aṣọ-òdodó, gbá ãtàn mọra.

6. Nitori aiṣedede ọmọbinrin awọn enia mi tobi jù ẹ̀ṣẹ Sodomu lọ, ti a bì ṣubu ni iṣẹju, laisi iṣiṣẹ ọwọ ninu rẹ̀.

7. Awọn Nasire rẹ̀ mọ́ jù ẹ̀gbọn-owu, nwọn funfun jù wàra; irisi wọn pọn jù iyùn, apẹrẹ wọn dabi okuta Safire:

8. Oju wọn dudu jù ẽdu nisisiyi; a kò mọ̀ wọn ni ita: àwọ wọn lẹ mọ egungun wọn; o di gbigbẹ gẹgẹ bi igi.

9. Awọn ti a fi idà pa san jù awọn ti a fi ebi pa, ti ndaku, ti a gún wọn lara nitori aisi eso-oko.

10. Ọwọ awọn obinrin alãnu ti sè awọn ọmọ awọn tikarawọn: awọn wọnyi li ohun jijẹ fun wọn ni igba wahala ọmọbinrin awọn enia mi.

11. Oluwa ti ṣe aṣepe irunu rẹ̀; o ti dà ibinu gbigbona rẹ̀ jade, o ti dá iná ni Sioni, ti o si ti jo ipilẹ rẹ̀ run.

12. Awọn ọba aiye, ati gbogbo olugbe ilẹ-aiye, kò gbagbọ pe aninilara ati ọta iba ti wọ inu ẹnu-bode Jerusalemu.

Ẹk. Jer 4