14. Ki awa ki o máṣe jẹ ewe mọ́, ti a nfi gbogbo afẹfẹ ẹ̀kọ́ tì siwa tì sẹhin, ti a si fi ngbá kiri, nipa itanjẹ enia, nipa arekereke fun ọgbọnkọgbọn ati múni ṣina;
15. Ṣugbọn ki a mã sọ otitọ ni ifẹ, ki a le mã dàgbasoke ninu rẹ̀ li ohun gbogbo, ẹniti iṣe ori, ani Kristi:
16. Lati ọdọ ẹniti ara na ti a nso ṣọkan pọ, ti o si nfi ara mọra, nipa gbogbo orike ipese, (gẹgẹ bi iṣẹ olukuluku ẹya-ara ni ìwọn tirẹ̀) o nmu ara na bi si i fun idagbasoke on tikararẹ ninu ifẹ.
17. Njẹ eyi ni mo nwi, ti mo si njẹri ninu Oluwa pe, lati isisiyi lọ ki ẹnyin ki o máṣe rìn mọ́, ani gẹgẹ bi awọn Keferi ti nrin ninu ironu asan wọn,
18. Òye awọn ẹniti o ṣòkunkun, awọn ti o si ti di àjeji si ìwa-bi-Ọlọrun nitori aimọ̀ ti mbẹ ninu wọn, nitori lile ọkàn wọn:
19. Awọn ẹniti ọkàn wọn le rekọja, ti nwọn si ti fi ara wọn fun wọ̀bia, lati mã fi iwọra ṣiṣẹ ìwa-ẽri gbogbo.
20. Ṣugbọn a kò fi Kristi kọ́ nyin bẹ̃;
21. Bi o ba ṣe pe nitotọ li ẹ ti gbohùn rẹ̀, ti a si ti kọ́ nyin ninu rẹ̀, gẹgẹ bi otitọ ti mbẹ ninu Jesu:
22. Pe, niti iwa nyin atijọ, ki ẹnyin ki o bọ ogbologbo ọkunrin nì silẹ, eyiti o dibajẹ gẹgẹ bi ifẹkufẹ ẹ̀tan;
23. Ki ẹ si di titun ni ẹmi inu nyin;
24. Ki ẹ si gbé ọkunrin titun nì wọ̀, eyiti a da nipa ti Ọlọrun li ododo ati li iwa mimọ́ otitọ́.
25. Nitorina ẹ fi eke ṣiṣe silẹ, ki olukuluku nyin ki o mã ba ọmọnikeji rẹ̀ sọ otitọ, nitori ẹ̀ya-ara ọmọnikeji wa li awa iṣe.
26. Ẹ binu; ẹ má si ṣe ṣẹ̀: ẹ máṣe jẹ ki õrùn wọ̀ bá ibinu nyin:
27. Bẹni ki ẹ má ṣe fi àye fun Èṣu.
28. Ki ẹniti njale máṣe jale mọ́: ṣugbọn ki o kuku mã ṣe lãlã, ki o mã fi ọwọ́ rẹ̀ ṣiṣẹ ohun ti o dara, ki on ki o le ni lati pín fun ẹniti o ṣe alaini.